Exodus 27:9-19

Àgbàlá

9 a“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, 10pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú. 11Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.

12“Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá. 13Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, 14Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15Àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.

16“Àti fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà, pèsè aṣọ títa, mítà mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elése àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin. 17Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 18Àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni gíga àti mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mítà méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 19Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.

Copyright information for YorBMYO